Oriki Ilajo (Appelations of Ilajo Royal Family)

  1. Omo mehi, mado, melenla, abi ekon dodo
  2. Omo Oke, Omo Baba Ogido, Omo Ewo bi
  3. Omo tarunle wole, a tarun kere mu omi, abowo kan so so lugbo
  4. Omo olisu akaledoro be
  5. Omo olope li ogbagba, emu re totowo
  6. Omo olile pupa lo gbagba
  7. Omo agbe isu kon da hon ahe, elewusu jikitijikiti
  8. Omo oro ogbagba-Abejiwere were larun
  9. Omo amura ogun girigiri
  10. Omo ari damadama dalu
  11. Omo idu gakun, Banga doshi
  12. Leramo wosun
  13. Edu gaga layin efon
  14. A ko hon hi le tarigbon tari gbon
  15. Omo apotolowo ewo
  16. Omo olobi poroporo logiri, Olile l’ ogiri ogiri gbogbo Ilajo
  17. Omo Baba a jaruke ruke kowa ponnon
  18. Omo Baba gbade gun asi
  19. Omo ase oyaya bi oni egbon
  20. Omo mu omo ko ni ton tobo re
  21. Omo eleja oluwa ajiwerakun igun aborisa, ani gbongbo omo rorin
  22. Omo orokika amu ile li ho
  23. Omo ajola dagba perepere
  24. Omo onile jobujobu
  25. Omo alade lati Ife Oduduwa
  26. Omo Obaro Odide, Odidere kin gbeloko wajo
  27. Afo dede jagun ewi
  28. Wo jagun ewi wo jagun gonigon wojagun Tapa
  29. Omo ba yon ko hon ha lati Ile-Ife
  30. Omo Obaro Ogido, Omo ewo bi
  31. Omo Obaro Elete
  32. Omo Obaro Ojimonu
  33. Omo Obaro Mokelu
  34. Omo Obaro Ajinuhi Baba Odundun a hole dero, Okala lati orun amu haye je
  35. Omo Obaro Gbayero. Gbayero dowe A mu Owo onehiba fon fere
  36. Omo Obaro Oluyori ati Kekere Jeolu
  37. Ahun nije mo pamo aho
  38. Omo OObaro Oluowe, Ejisu lowe
  39. Omo ari pon no meji ya kon re
  40. Omo Obaro Olobayo, Obaro Ero potopoto Eropoto kemu sugbin, oroboto eta ni igo
  41. Omo ObaroObaro Olle Akikan ajegidigbanre
  42. Omo Obaro Ologbonyo Atobatele. Ologbonyo yo bere, atehibi ayete hi Ologbon dori eja mu
  43. Omo obaro Michael Olobayo. Obaro ero keji, Ojoyelijinjinrin, atomobaba se ata, igbakeji Orisa, irin kekere komo eyin ata ponoletayin tayin alahuwa lahayin, Olisuru, Olotito Oloye, Omolope ejetise. Ilajo Sarki, Ilajo Banga dosi, Ilajo Wosin, Ilajo Gaaba Idu

STILL NOT SURE WHAT TO DO?

We are glad that you preferred to contact us. Please fill our short form and one of our friendly team members will contact you back.

Form is not available. Please visit our contact page.
X
CONTACT US